Matthew 21:1-9

Fífi ayọ̀ wọlé

1 aBí wọ́n ti súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé itòsí ìlú Betfage ní orí òkè Olifi, Jesu sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì, 2Ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí ìletò tó wà ni tòsí yín, ẹ̀yin yóò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ti wọ́n so pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. 3Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sá à wí pé, Olúwa fẹ́ lo wọn, òun yóò sì rán wọn lọ.”

4Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé:

5 b“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé,
‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”
6Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti sọ fún wọn 7Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jesu si jókòó lórí rẹ̀. 8 cỌ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà. 9 dỌ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé,

“Hosana fún ọmọ Dafidi!”

“Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!”

“Hosana ní ibi gíga jùlọ!”
Copyright information for YorBMYO